Emi ó si bère lọwọBaba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai, JOHN 14:16
1. Tan ihin na kale, jakejado aye,
K‘awon ti eru npa, mo pe igbala de:
K‘awon ti se ti Krist‘, so ihin ayo na,
Olutunu ti de.
Olutunu ti de, Olutunu ti de,
Emi lat' oke wa, ileri Baba wa;
Tan ihin na kale, jakejado aye,
Olutunu ti de.
2. Oba awon oba, wa f'iwosan fun wa,
O wa ja ide wa, O mu igbala wa,
K‘olukuluku wa, korin isegun pe:
Olutunu ti de.
3. Ife iyanu nla, a! mba le royin na,
Fun gbogbo eniyan, ebun or‘ofe Re;
Emi omo egbe, di omo igbala,
Olutunu ti de
4. Gbe orin ‘yin soke, s‘Olurapada wa,
K‘awon mimo loke, jumo ba wa gberin
Yin ife Re titi, ife ti ko le ku,
Olutunu ti de.
Amin.
0 Comments